2 Corinthians 9

1 aNísinsin yìí, nípa ti ìpín fún ni fún àwọn ènìyàn mímọ́, kò tún yẹ mọ́ fún mi láti kọ̀wé sí yin ju bẹ́ẹ̀ lọ. 2 bNítorí mo mọ ìtara láti ṣe ìrànlọ́wọ́ yín, èyí tí mo ti ṣògo fún àwọn ará Makedonia nítorí yín, pé, àwọn ara Akaia ti múra tan níwọ̀n ọdún kan tí ó kọjá ìtara yín sì ti rú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè. 3 cṢùgbọ́n mo ti rán àwọn arákùnrin, kí ìṣògo wa nítorí yín má ṣe jásí asán ní ti ọ̀ràn yìí; pé gẹ́gẹ́ bí mó ti wí, kí ẹ̀yin lè múra tẹ́lẹ̀. 4Kí ó má ba à jẹ́ pé, bí àwọn nínú ara Makedonia bá bá mi wá, tí wọ́n sì bá yín ní àìmúra sílẹ̀, ojú a sì tì wá kì í ṣe ẹ̀yin, ní ti ìgbẹ́kẹ̀lé yìí. 5Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ́bi ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti a fi ìkùnsínú ṣe.

Ìfúnrúgbìn tọkàntọkàn

6Ṣùgbọ́n èyí ni mo wí pé: Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn kín ún, kín ún ni yóò ká; ẹni tí ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká. 7 dKí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọkàn rẹ̀; kì í ṣe àfi ìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọdọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ. 8 eỌlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore-ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo. 9 fGẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé:

“Ó tí fọ́nká; ó ti fi fún àwọn tálákà;
Òdodo rẹ̀ dúró láéláé.”
10 gǸjẹ́ ẹni tí ń fi irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i. 11Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa.

12Nítorí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìsìn yìí kò kún ìwọ̀n àìní àwọn ènìyàn mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ sí Ọlọ́run. 13 hNítorí ìdúró yin lábẹ́ ìdánwò iṣẹ́ ìsìn yìí, wọn yóò yin Ọlọ́run lógo fún ìgbọ́ràn yín ní gbígba ìhìnrere Kristi àti nípa ìlawọ́ ìdáwó yín fún wọn àti fún gbogbo ènìyàn. 14Àti nínú àdúrà fún un yín, ọkàn wọn ń ṣe àfẹ́rí yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ti ń bẹ nínú yín. 15 iỌpẹ́ ni fún Ọlọ́run nítorí aláìlèfẹnusọ ẹ̀bùn rẹ̀!

Copyright information for YorBMYO